Yoruba/EÌdeÌ

Kú Àbọ̀ sí Ètò-Ìkànìyàn ti Ọdún 2011.

Ní ọjọ́ Àìkú, ọjọ́ Kẹwàá, où Kẹrin ni ẹ̀kùnrẹ́rẹ́ Ètò-Ìkànìyàn àwọn Olùgbé yóò wáyé ní orílẹ̀-èdè Ireland. Ètò-ìkànìyàn náà yóò ka ẹni kọ̀ọ̀kan tí n bẹ ní Orílẹ̀-èdè Ireland ní alẹ́ ọjọ́ náà. Àbáyọrí rẹ̀ yóò wúlò fún pàtàkì irò, ó sì wà fún gbogbo ènìyàn láti lò. Àbájáde ètò-ìkànìyàn àkọ́kọ́ yóò jáde nínú où Kẹfà ọdún yìí.


Jọ̀wọ́ tẹ orí àwọn àsomọ́ ìsàlẹ̀ yìí fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé lórí Ètò-Ìkànìyàn ọdún 2011:

Bojúwò ó/e àgbésọ̀ fọ́ọ́mù fún ètò-ìkànìyàn náà ní ìtumọ̀sí-èdè míràn níbí.

Bojúwò ó /e àgbésọ̀ Ìwé-pélébé fún Ètò-ìkànìyàn

Bojúwò ó /e àgbésọ̀ Irohin nipa Ètò-ìkànìyàn ti ọdun 2006 “Fun Awọn ti Ki i e Ọmọ-Ilẹ̀ Ireland” (ní èdè Gẹ̀ẹ́sì nìkan).

 

Àlàyé lórí Ètò-ìkànìyàn ọdún 2011

 

Kín ni ètò-ìkànìyàn ?

Ètò-ìkànìyàn jẹ́ kíka gbogbo ènìyàn tí n bẹ ní orílẹ̀-èdè yìí ní alẹ́ ọjọ́ ètò-ìkànìyàn.  Ní alẹ́ ọjọ́ ètò-ìkànìyàn, gbogbo ènìyàn nínú orílẹ̀-èdè náà ní ó gbọ́dọ̀ kópa nínú ètò-ìkànìyàn náà, tí ó sì gbọ́dọ̀ jẹ́ ara iye àwọn ènìyàn àti ibùgbé tí a kà lábẹ́ òfin, èyí tí ó máa n wáyé ní ọdún márùn ún-márùn ún ní ilẹ̀ Ireland.

 

Nígbà wo ní ètò-ìkànìyàn tí ó kàn?

Ètò-ìkànìyàn tí n bọ̀ lọ́nà yóò wáyé ní alẹ́ Ọjọ́ Àìkú, Ọjọ́ Kẹwàá, où Kẹrin, ọdún 2011. Ènìyàn kọ̀ọ̀kan tí n bẹ ní orílẹ̀-èdè yìí ní ọjọ́ náà ní ó gbọ́dọ̀ wà lórí fọ́ọ̀mù ètò-ìkànìyàn kan. A gbọ́dọ̀ kà ọ́ lórí fọ́ọ̀mù ètò-ìkànìyàn kan níbikíbi ní ilẹ̀ Ireland – bóyá nínú ilé rẹ, tàbí o wà pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ àti ìbátan, tàbí ní ilé-ìwòsàn, abbl.

 

Njẹ mo ní láti kọ fọ́ọ̀mù̀ náà?

Bẹ́ẹ̀ ni. ẹnikẹ́ni tí ó wà ní orílẹ̀-èdè yìí ní alẹ́ ọjọ́ ètò-ìkànìyàn gbọ́dọ̀ kópa nínú rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni òfin sọ. Ìlanilọ́yẹ̀ tí ètò-ìkànìyàn náà máa n pèsè e pàtàkì fún ísètò fún ọjọ́-iwájú gbogbo wa, torí náà, o e pàtàkì kí ẹ̀nìkọ̀ọ̀kan kópa nínú rẹ̀.

 

Kín ni mo ní láti e?

Akọ̀wé ètò-ìkànìyàn rẹ yóò fi fọ́ọ̀mù ètò-ìkànìyàn rẹ sọwọ́ sí ìbùgbé rẹ ní bí i ọ̀ẹ̀ 3 sí 4 saájú Alẹ Ọjọ́ Ètò-Ìkànìyàn náà. O ní láti pa fọ́ọ̀mù yìí mọ́ síbì kan títí di ọjọ́ ètò-ìkànìyàn. Inú akọ̀wé náà yóò dùn láti dáhùn ìbéèrè yòówù tí o bá ní nípa fọ́ọ̀mù náà.

Ní ọjọ ètò-ìkànìyàn, o ní lati kọ fọ́ọ̀mù náà parí fún ènìyan kọ̀ọ̀kan nínú ìdílé rẹ, kí o sì buwọ́lu ìbúra tí ó wà ní ìparí fọọmi náà, nigba ti o bá kọ ọ́ parí. Jọwọ fi pamọ daadaa títí tí a ó fi gbà á padá lọwọ rẹ. Akọ̀wé ètò-ìkànìyàn rẹ yóò pè ọ ní bí i ọ̀ẹ̀ 2 sí 3 lẹ́yìn ètò-ìkànìyàn náà lati gba fọọmu náà lọwọ rẹ. Inú wọn yoo sí dùn pẹ̀lú lati ran ọ lọwọ ti o ba ni ìòro yoowu nipa kíkọ fọọmu náà. O le yẹ ìdánimọ̀ akọwe naa nipa bibeere pe ki wọn fi Kaadi ìdánimọ̀ wọn hàn ọ.

 

Njẹ̀ ó boni ní àírí?

Bẹ́ẹ̀ ni. Gbogbo idahun tí o bá kọ sori fọ́ọ̀mù ètò-ìkànìyàn náà pátá ní a kò ní í fi hàn ẹni kankan, fún pàtàkì irò níkan ni a ó lò ó fún. A kò ní fi àlàyé kankan nípa rẹ fún àjọ tabi aojú ìjọba kankan. Òfin e ìlérí fún ọ bẹ́ẹ̀!

 

Kín ni ètò-ìkànìyàn wúlò fún?

A n lo ètò-ìkànìyàn naa lati pese ìfitónilétí nípa awọn eniyan ti n gbe ní ilẹ Ireland. Ìjọba ti ẹlẹ́kùn-jẹkùn ati ti ìbílẹ̀, awọn ilé-iẹ okoòwò, awọn agbegbe ìbílẹ̀ ati awọn míràn ni yoo lò ìfitónilétí yìí, lati ràn wọ́n lọwọ ki wọn lè è awọn ipinnu, fún awọn ètò ọjọ-ọ̀la nipa ọrọ ẹ̀kọ́, ti ílera, ìpèsè-iẹ́, ti ìrìnnà-ọkọ̀ ati awọn ìpèsè awọn ànfààní míràn. Ìfitónilétí náà kò ní í e òfófo awọn àlàyè nipa ara-ẹni. Tẹ orí ibí fún àlàyé sí ii ní èdè Gẹ̀ẹ́sì nípa awọn ànfààní ètò-ìkànìyàn náà.

 

Níbo ni mo ti lè rí ìrànwọ́ gbà?

Akọ̀wé ètò-ìkànìyàn rẹ wà fún ọ lati èrànwọ́ fún ọ, tí inú rẹ̀ yóò sì dùn láti dáhùn ìbéèrè yòówù tí o bá ní nípa ètò-ìkànìyàn náà tabi nípa kíkọ fọ́ọ̀mù náà.

Ìtumọ̀sí-èdè míràn an fọ́ọ̀mù ètò-ìkànìyàn tún n bẹ ní àwọn èdè 21 tí wọn wà ní ìsàlẹ̀ yìí ní èdè: èdè Poland, èdè Romania, èdè Lithuania, èdè Faranse, èdè Jamani, èdè Russia, èdè Spain, èdè Yoruba, èdè China, èdè Slovakia, èdè Hungari, èdè Potogi, èdè Larubawa, èdè Itali, èdè Czechoslovakia, èdè Latvia, èdè Estonia, èdè Bulgaria, èdè Hindu, èdè Urdu àti èdè ilSwahili. Ìwọ yóò rí àlàyé tí ó wà ní èdè kọ̀ọ̀kan nípa títẹ orí ibí.

O lè tẹ orí àwọn àsomọ́ ìsàlẹ̀ yìí lati rí àwọn àlàyé gbà sí i nípa fọ́ọ̀mù Ètò-ìkànìyàn náà ní èdè Gẹ̀ẹ́sì, àti bí a e n kọ ọ́ ní:

Torí náà, kọ awọn ohun tí ó yẹ sínú fọ́ọ̀mù ètò-ìkànìyàn náà ní Ọjọ́ Àìkú, Ọjọ́ Kẹwàá, où Kẹrin, ọdún 2011 kí o sì èrànwọ́ lati rí i dájú pé Ètò-Ìkànìyàn 2011 yọrí sí rere.